back to all blogs

All Blogs

Àwọn oníṣòwò kọ̀ọ̀kan pín àwọn ìrírí wọn bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ Dillali fún ìṣowò wọn lọ́wọ́.

Jun 2022

4 mins read

Yoruba

Àwọn oníṣòwò kọ̀ọ̀kan pín àwọn ìrírí wọn bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ Dillali fún ìṣowò wọn lọ́wọ́.

Dillali ń ṣe ìrànwọ́ fún àwọn oníṣòwò bíi ẹgbẹ̀rún mọ́kànlà láti ṣe àbójútó ìṣòwò wọn dáadáa lọfẹ. Àwọn oníṣòwò kọ̀ọ̀kan pín àwọn ìrírí wọn bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ Dillali fún ìṣowò wọn lọ́wọ́.

Ni ìsàlẹ̀ yìí ni à ó ti rí àwọn ìjẹ́rísí kọ̀ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò :

HAUWA M BAKO - Olùdásilẹ̀ HB GREEN ACRES FARMS

Mo ní oko ànàmọ́, èyí tí ó jẹ́ òwò tí ó ní ìgbà. A nílò ojútùú sí títọpa àwọn ọjà títà wa. Ní pàtàkì fún àwọn oníbárà tí wọn kò san owó pé. Dillali ń ṣe gbogbo ìṣirò fún wa. Èyí tí ó dára jù ni pé, mo lè ríi bóyá ìṣowò wa ní èrè, àti àwọn tó jẹ wá lówó.

GRACE IDEAWOR- ONÍṢÒWÒ

Dillali máa ń bá mi tọpa àwọn oníbárà wá dáadáa, láti ní àtẹ̀lé tó péye. Báyìí mo mọ gbogbo àwọn tí a ti bá ṣiṣé, Mo lè fi ìrọ̀rùn padà lọ wo àwọn tí wọn kò tíì san owó sí orí ìwé risiti wọn.

IMAM A - ONÍṢẸ́ỌWỌ́

Mo jẹ́ oníṣòwò tí ó máa ń ṣiṣẹ́ ṣaápọn tí mo sì ń fi púpò nínú àkókò tọpinpin ìdíyelé oníbárà tàbí tọpinpin àwọn ìnáwó. Mo sì nílò ẹni tí yóò ràn mí lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí. Dillali ni ojútùú tí ó dára jù lọ. Ó ti ṣe ìrànwọ́ fún mi nípa mímú adínkù bá àkókò tí mo fi ń tọpínpín ìnáwó mi àti mímú adínkù bá ìdíyelé.

HADIYA - OLÙDÁSÍLẸ̀ Rhuminas Language Hub

Ẹ̀rọ Dillali yìí rọrùn gan-an láti ṣètò. Ó tayọ fún òwò kékeré. Mo fẹ́ràn bí mo ṣe lè ṣe àfiránsẹ́ àwọn ìwé risiti nípasẹ̀ lílo ẹ̀rọ ayélujára Whatsapp àti imeeli àti láti tún ṣe àfiránsẹ́ olùránnilétí fún àwọn oníbárà mi láti san owó nígbà tí ó bá yẹ.

Bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí lọfẹ